2 Samuel 15:34 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí o bá pada sí ìlú, tí o sì sọ fún Absalomu, ọba, pé o ti ṣetán láti sìn ín pẹlu ẹ̀mí òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí o ti sin èmi baba rẹ̀, nígbà náà ni o óo ní anfaani láti bá mi yí ìmọ̀ràn Ahitofeli po.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi iwọ ba si pada si ilu, ti o si wi fun Absalomu pe, Emi o ṣe iranṣẹ rẹ, ọba, gẹgẹ bi emi ti ṣe iranṣẹ baba rẹ nigba atijọ, bẹ̃li emi o si jẹ iranṣẹ rẹ nisisiyi: ki iwọ ki o si bà ìmọ Ahitofeli jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ìwọ bá sì padà sí ìlú, tí o sì wí fún Ábúsálómù pé, ‘Èmi ó ṣe ìránṣẹ́ rẹ ọba, gẹ́gẹ́ bí èmi ti ṣe ìránṣẹ́ baba rẹ nígbà àtíjọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó sì jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ nísínsinyìí,’ kí ìwọ sì bá ìmọ̀ Áhítófélì jẹ́.