2 Samuel 15:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Absalomu á tún wá fi kún un pé, “A! Bí wọ́n bá fi mí ṣe adájọ́ ní ilẹ̀ yìí ni, bí ẹnikẹ́ni bá ní èdè-àìyedè kan pẹlu ẹlòmíràn, tabi tí ẹnìkan bá fẹ́ gba ohun tíí ṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀, wọn ìbá máa tọ̀ mí wá, ǹ bá sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Absalomu a si wipe, A ba jẹ fi mi ṣe onidajọ ni ilẹ yi! ki olukuluku ẹniti o ni ẹjọ tabi ọ̀ran kan ba le ma tọ̀ mi wa, emi iba si ṣe idajọ otitọ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábúsálómù a sì wí pé, “À bá jẹ́ fi mi ṣe onídájọ́ ní ilẹ̀ yìí! Kí olúkúlùkù ẹni tí ó ní ẹjọ́ tàbí ọ̀ràn kan báà lè máa tọ̀ mí wá, èmi ìbá sì ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún un.”