2 Samuel 16:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní gẹ́rẹ́ tí Dafidi kọjá góńgó orí òkè náà, Siba, iranṣẹ Mẹfiboṣẹti pàdé rẹ̀, ó ń da àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bíi mélòó kan bọ̀ tí ó di igba (200) burẹdi rù, pẹlu ọgọrun-un ṣiiri èso resini, ati ọgọrun-un ṣiiri èso tútù mìíràn ati àpò aláwọ kan tí ó kún fún ọtí waini.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NIGBATI Dafidi si fi diẹ kọja ori oke na, si wõ, Siba iranṣẹ Mefiboṣeti si mbọ̀ wá ipade rẹ̀, ti on ti kẹtẹkẹtẹ́ meji ti a ti dì li asá, ati igba iṣu akara li ori wọn, ati ọgọrun ṣiri ajara gbigbẹ, ati ọgọrun eso ẹrùn, ati igò ọti-waini kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Dáfídì sì fi díẹ̀ kọjá orí òkè náà, sì wò ó, Ṣíbà ìránṣẹ́ Mefíbóṣétì sì ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀, òun àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì tí a ti dì ní gàárì, àti igba ìṣù àkàrà lórí wọn, àti ọgọ́rùn-ún ṣírì àjàrà gbígbẹ, àti ọgọ́rùn ún èṣo ẹ̀rún, àti ìgò ọtí-wáìnì kan.