2 Samuel 16:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ọba dáhùn pé, “Kò sí ohun tí ó kan ẹ̀yin ọmọ Seruaya ninu ọ̀rọ̀ yìí. Kí ni n óo ti ṣe yín sí, ẹ̀yin ọmọ Seruaya? Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni ó sọ fún un pé kí ó máa ṣépè lé mi, ta ló ní ẹ̀tọ́ láti bèèrè pé, kí ló dé tí ó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si wipe, Kili emi ni fi nyin ṣe, ẹnyin ọmọ Seruia? jẹ ki o ma bu bẹ̃, nitoriti Oluwa ti wi fun u pe: Bu Dafidi. Tani yio si wipe, Nitori kini iwọ fi ṣe bẹ̃?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì wí pé, “Kín ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yín ọmọ́ Séríià? Bí ó bá ń bú èébú, nítorí tí OLÚWA ti wí fún un pé: ‘Bú Dáfídì!’ Ta ni yóò sì wí pé, ‘kín ni ìdí tí o fi ṣe bẹ́ẹ̀.’ ”