2 Samuel 16:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bá ń bá tiwọn lọ, Ṣimei sì ń tẹ̀lé wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji òkè náà, bí ó ti ń tẹ̀lé wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣépè, ó ń sọ òkúta lù ú, ó sì ń da erùpẹ̀ sí wọn lára.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si nlọ li ọ̀na, Ṣimei si nrìn li ẹba oke ti o wà li ẹgbẹ rẹ̀, o si nyan ẽbu bi o ti nlọ, o si nsọ ọ li okuta, o si nfún erupẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń lọ ní ọ̀nà, Ṣíméhì sì ń rìn lẹ́bá òkè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì ń yan èébú bí ó ti ń lọ, ó sì ń sọ ọ́ lókúta, ó sì ń fọ́n erùpẹ̀.