2 Samuel 16:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Huṣai dáhùn pé, “Ẹ̀yìn ẹnikẹ́ni tí OLUWA, ati àwọn eniyan wọnyi, ati gbogbo Israẹli bá yàn ni mo wà. Tirẹ̀ ni n óo jẹ́, n óo sì dúró tì í.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Huṣai si wi fun Absalomu pe, Bẹ̃kọ nitori ẹniti Oluwa, ati gbogbo awọn enia yi, ati gbogbo awọn ọkunrin Israeli ba yàn, tirẹ̀ li emi o jẹ, on li emi o si ba joko.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Húṣáì sì wí fún Ábúsálómù pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ nítorí ẹni tí OLÚWA, àti gbogbo àwọn ènìyàn yìí, àti gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì bá yàn, tirẹ̀ lèmi ó jẹ́, òun lèmi ó sì bá jókòó.