2 Samuel 16:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi ọba bi í pé, “Kí ni o fẹ́ fi gbogbo nǹkan wọnyi ṣe?” Siba dá a lóhùn pé, “Mo mú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọnyi wá kí àwọn ìdílé Kabiyesi lè rí nǹkan gùn, mo mú burẹdi, ati èso wọnyi wá kí àwọn ọdọmọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ lè rí nǹkan jẹ; ati ọtí waini, kí àwọn tí àárẹ̀ bá mú ninu aṣálẹ̀ lè rí nǹkan mu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si wi fun Siba pe, Kini wọnyi? Siba si wipe, Kẹtẹkẹtẹ wọnyi ni fun awọn ara ile ọba lati ma gùn; ati akara yi, ati eso ẹrùn yi ni fun awọn ọdọmọdekunrin lati jẹ; ati ọti-waini yi ni fun awọn alãrẹ ni ijù lati mu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì wí fún Ṣíbà pé, “Kí ni wọ̀nyí?” Ṣíbà sì wí pé, “Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ̀nyí ni fún àwọn ará ilé ọba láti máa gùn àti àkàrà yìí, àti èso ẹ̀rún yìí ni fún àwọn ọdọmọdékùnrin láti jẹ; àti ọtí-wáìnì yìí ni fún àwọn aláàárẹ̀ ní ijù láti mu.”