2 Samuel 16:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ahitofeli dáhùn pé, “Wọlé lọ bá àwọn obinrin baba rẹ, tí ó fi sílẹ̀ láti máa tọ́jú ààfin, kí o sì bá wọn lòpọ̀. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yóo wá gbà pé o ti kẹ̀yìn sí baba rẹ, ọkàn gbogbo àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ yóo sì balẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ahitofeli si wi fun Absalomu pe, Wọle tọ awọn obinrin baba rẹ lọ, awọn ti o fi silẹ lati ma ṣọ ile, gbogbo Israeli yio si gbọ́ pe, iwọ di ẹni-irira si baba rẹ, ọwọ́ gbogbo awọn ti o wà lọdọ rẹ yio si le.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Áhítófélì sì wí fún Ábúsálómù pé, “Wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ lọ, tí ó fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé, gbogbo Ísírẹ́lì yóò sì gbọ́ pé, ìwọ di ẹni-ìríra sí baba rẹ, ọwọ́ gbogbo àwọn tí ó wà lọdọ rẹ yóò sì le.”