2 Samuel 16:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní àkókò náà, ìmọ̀ràn tí Ahitofeli bá dá, ni àwọn eniyan máa ń gbà, bí ẹni pé Ọlọrun gan-an ni ó ń sọ̀rọ̀; Dafidi ati Absalomu pàápàá a máa tẹ̀lé ìmọ̀ràn rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Imọ̀ Ahitofeli ti ima gbà nijọ wọnni, o dabi ẹnipe enia mbere nkan li ọwọ́ Ọlọrun: bẹ̃ni gbogbo ìmọ Ahitofeli fun Dafidi ati fun Absalomu si ri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìmọ̀ Áhítófélì tí ó máa ń gbà ni ìgbà náà, ó dàbí ẹni pé ènìyàn béèrè nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run: bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ìmọ̀ Áhítófélì fún Dáfídì àti fún Ábúsálómù sì rí.