2 Samuel 16:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọba tún bi í pé, “Níbo ni Mẹfiboṣẹti, ọmọ ọmọ Saulu, ọ̀gá rẹ wà?” Siba dá a lóhùn pé, “Mẹfiboṣẹti dúró sí Jerusalẹmu; nítorí ó dá a lójú pé, nisinsinyii ni àwọn ọmọ Israẹli yóo dá ìjọba Saulu baba-baba rẹ̀ pada fún un.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si wipe, Ọmọ oluwa rẹ da? Siba si wi fun ọba pe, Wõ, o joko ni Jerusalemu; nitoriti o wipe, Loni ni idile Israeli yio mu ijọba baba mi pada fun mi wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì wí pé, “Ọmọ olúwa rẹ dà?” Ṣíbà sì wí fún ọba pé, “Wò ó, ó jókòó ní Jérúsálẹ́mù; nítorí tí ó wí pé, ‘Lónìí ni ìdílé Ísírẹ́lì yóò mú ìjọba baba mi padà wá fún mi.’ ”