2 Samuel 16:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìwọ tí o gba ìjọba mọ́ Saulu lọ́wọ́, OLUWA ń jẹ ọ́ níyà nisinsinyii, fún ọpọlọpọ eniyan tí o pa ninu ìdílé Saulu. OLUWA sì ti fi ìjọba rẹ fún Absalomu, ọmọ rẹ, ìparun ti dé bá ọ, nítorí pé apànìyàn ni ọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa mu gbogbo ẹjẹ idile Saulu pada wá si ori rẹ, ni ipo ẹniti iwọ jọba; Oluwa ti fi ijọba na le Absalomu ọmọ rẹ lọwọ: si wõ, ìwa buburu rẹ li o mu eyi wá ba ọ, nitoripe ọkunrin ẹjẹ ni iwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA mú gbogbo ẹ̀jẹ̀ ìdílé Ṣọ́ọ̀lù padà wá sí orí rẹ, ní ipò ẹni tí ìwọ jọba; OLÚWA ti fi ijọba náà lé Ábúsálómù ọmọ rẹ lọ́wọ́: sì wò ó, ìwà búburú rẹ ni ó mú èyí wá bá ọ, nítorí pé ọkùnrin ẹ̀jẹ̀ ni ìwọ.”