2 Samuel 17:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà, ẹ̀rù yóo ba àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju jùlọ ninu àwọn eniyan rẹ, tí wọ́n sì láyà bíi kinniun; nítorí pé, gbogbo eniyan ní Israẹli ni ó mọ̀ pé akọni jagunjagun ni baba rẹ, akikanju sì ni àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti o si ṣe alagbara, ti ọkàn rẹ̀ si dabi ọkàn kiniun, yio si rẹ̀ ẹ: nitori gbogbo Israeli ti mọ̀ pe alagbara ni baba rẹ, ati pe, awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ jẹ alagbara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tí ó sì ṣe alágbára, tí ọkàn rẹ̀ sì dàbí ọkàn kìnnìun, yóò sì rẹ̀ ẹ́: nítorí gbogbo Ísírẹ́lì ti mọ̀ pé alágbára ni baba rẹ, àti pé, àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ jẹ́ alágbára.