2 Samuel 17:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìmọ̀ràn tèmi ni pé kí o kó gbogbo àwọn ọmọ ogun jọ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli láti Dani títí dé Beeriṣeba, kí wọ́n pọ̀ bíi yanrìn etí òkun. Ìwọ gan-an ni kí o ṣáájú wọn lọ sí ogun náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina emi damọ̀ran pe, Ki gbogbo Israeli wọjọ pọ̀ sọ̀dọ rẹ, lati Dani titi dé Beerṣeba, gẹgẹ bi yanrin ti o wà leti okun fun ọ̀pọlọpọ; ati pe, ki iwọ tikararẹ ki o lọ si ogun na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà èmi dámọ̀ràn pé: Kí gbogbo Ísírẹ́lì wọ́jọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ, láti Dánì títí dé Bééríṣébà, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn létí òkun fún ọ̀pọ̀lọpọ̀; àti pé, kí ìwọ tìkárarẹ ó lọ sí ogun náà.