2 Samuel 17:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ó bá sá wọ inú ìlú kan, àwọn ọmọ Israẹli yóo fi okùn fa ìlú náà lulẹ̀ sinu àfonífojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀. Ẹyọ òkúta kan ṣoṣo kò ní ṣẹ́kù sórí òkè náà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ba si bọ si ilu kan, gbogbo Israeli yio si mu okùn wá si ilu na, awa o si fà a lọ si odo, titi a kì yio fi ri okuta kekeke kan nibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí o bá sì bọ́ sí ìlú kan, gbogbo Ísírẹ́lì yóò mú okùn wá sí ìlú náà, àwa ó sì fà á lọ sí odo, títí a kì yóò fi rí òkúta kékeké kan níbẹ̀.”