2 Samuel 17:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Absalomu ati gbogbo Israẹli dáhùn pé, “Ìmọ̀ràn ti Huṣai dára ju ti Ahitofeli lọ,” nítorí pé OLUWA ti pinnu láti yí ìmọ̀ràn rere tí Ahitofeli mú wá pada, kí ibi lè bá Absalomu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Absalomu ati gbogbo ọkunrin Israeli si wipe, Ìmọ Huṣai ara Arki sàn jù ìmọ Ahitofeli lọ. Nitori Oluwa fẹ lati yi ìmọ rere ti Ahitofeli po, nitori ki Oluwa ki o le mu ibi wá sori Absalomu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábúsálómù àti gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì sì wí pé, “Ìmọ̀ Húṣáì ará Áríkì sàn ju ìmọ̀ Áhítófélì lọ! Nítorí OLÚWA fẹ́ láti yí ìmọ̀ rere ti Áhítófélì po.” Nítorí kí OLÚWA lè mú ibi wá sórí Ábúsálómù.