2 Samuel 17:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Huṣai tún fi kún un pé, kí wọ́n ranṣẹ kíákíá lọ sọ fún Dafidi pé, kò gbọdọ̀ sùn níbi tí wọ́n ti ń ré odò Jọdani kọjá ninu aṣálẹ̀ ní òru ọjọ́ náà. Ó gbọdọ̀ kọjá sí òdìkejì odò lẹsẹkẹsẹ kí ọwọ́ má baà tẹ̀ ẹ́ ati àwọn eniyan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì pa wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina yara ranṣẹ nisisiyi ki o si sọ fun Dafidi pe, Máṣe duro ni pẹtẹlẹ ijù nì li alẹ yi, ṣugbọn yara rekọja, ki a má ba gbe ọba mì, ati gbogbo awọn enia ti o mbẹ lọdọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà yára ránṣẹ́ nísinsin yìí kí o sì sọ fún Dáfídì pé, ‘Má ṣe dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ijù náà lálẹ́ yìí, ṣùgbọ́n yára rékọjá kí a má báa gbé ọba mì, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.’ ”