2 Samuel 17:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ọmọkunrin kan rí wọn, ó sì sọ fún Absalomu. Jonatani ati Ahimaasi bá sáré lọ fi ara pamọ́ ní ilé ọkunrin kan ní Bahurimu. Ọkunrin yìí ní kànga kan ní àgbàlá ilé rẹ̀. Àwọn mejeeji bá kó sinu kànga náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ọdọmọdekunrin kan ri wọn, o si wi fun Absalomu: ṣugbọn awọn mejeji si yara lọ kuro, nwọn si wá si ile ọkunrin kan ni Bahurimu, ẹniti o ni kanga kan li ọgbà rẹ̀, nwọn si sọkalẹ si ibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ọdọmọdékùnrin kan rí wọn, ó sì wí fún Ábúsálómù: ṣùgbọ́n àwọn méjèèjì sì yára lọ kúrò, wọ́n sì wá sí ilé ọkùnrin kan ní Báhúrímù, ẹni tí ó ní kànga kan ní ọgbà rẹ̀, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ sí ibẹ̀.