2 Samuel 17:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ọkunrin náà lọ tán, Ahimaasi ati Jonatani jáde ninu kànga, wọ́n sì lọ ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Dafidi. Wọ́n sọ ohun tí Ahitofeli ti gbèrò láti ṣe sí Dafidi. Wọ́n ní kí ó yára, kí ó rékọjá sí òdìkejì odò náà kíá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, lẹhin igbati nwọn yẹra kuro tan, awọn si jade kuro ninu kanga, nwọn si lọ, nwọn si rò fun Dafidi ọba, nwọn si wi fun Dafidi pe, Dide ki o si goke odo kánkán: nitoripe bayi ni Ahitofeli gbìmọ si ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti lọ tán, àwọn ọkùnrin náà sì jáde kúrò nínú kànga, wọ́n sì lọ wọ́n sì rò fún Dáfídì ọba. Wọ́n sọ fún Dáfídì pé, “Dìde kí o sì gòkè odò kánkán: nítorí pé bayìí ni Áhítófélì gbìmọ̀ sí ọ.”