2 Samuel 17:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
oyin, omi wàrà, ati wàrà sísè. Wọ́n sì kó aguntan wá pẹlu, láti inú agbo wọn fún Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀, kí wọ́n lè rí nǹkan jẹ. Nítorí wọ́n rò pé yóo ti rẹ̀ wọ́n, ebi yóo ti máa pa wọ́n, òùngbẹ yóo sì ti máa gbẹ wọ́n, ninu aṣálẹ̀ tí wọ́n wà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati oyin, ati ori-amọ, ati agutan, ati wàrakasi malu, wá fun Dafidi, ati fun awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ lati jẹ: nitoriti nwọn wi pe, ebi npa awọn enia, o si rẹ̀ wọn, orungbẹ si ngbẹ wọn li aginju.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti oyin, àti òrí-àmọ́, àti àgùntàn, àti wàràǹkàsì màlúù, wá fún Dáfídì àti fún àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, láti jẹ: nítorí tí wọ́n wí pé, “Ebi ń pa àwọn ènìyàn, ó sì rẹ̀ wọ́n, òǹgbẹ sì ń gbẹ wọ́n ní ihà.”