2 Samuel 17:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣebí o mọ̀ pé, akikanju jagunjagun ni baba rẹ, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀? Ara kan wọ́n báyìí, wọn yóo sì rorò ju abo ẹkùn beari tí ọdẹ jí lọ́mọ kó lọ. Bẹ́ẹ̀ sì ni jagunjagun tí ó ní ọpọlọpọ ìrírí ni baba rẹ, kò sì ní sùn lọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ní alẹ́ yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Huṣai si wipe, Iwọ mọ̀ baba rẹ ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe alagbara ni nwọn, nwọn si wà ni kikoro ọkàn bi amọ̀tẹkun ti a gbà li ọmọ ni igbẹ: baba rẹ si jẹ jagunjagun ọkunrin, kì yio ba awọn enia na gbe pọ̀ li oru.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Húṣáì sì wí pé, “Ìwọ mọ baba rẹ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé alágbára ni wọ́n, wọ́n sì wà ní Kíkorò ọkàn bí àmọ̀tẹ́kùn tí a gbà ní ọmọ ni pápá: baba rẹ sì jẹ́ jagunjagun ọkùnrin kì yóò bá àwọn ènìyàn náà gbé pọ̀ lóru.