2 Samuel 17:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bóyá bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, ninu ihò ilẹ̀ níbìkan ni ó wà tabi ibòmíràn. Bí Dafidi bá kọlu àwọn eniyan rẹ, tí wọ́n sì pa díẹ̀ ninu wọn, àwọn tí wọ́n bá gbọ́ yóo wí pé wọ́n ti ṣẹgun àwọn eniyan Absalomu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i o ti fi ara rẹ̀ pamọ nisisiyi ni iho kan, tabi ni ibomiran: yio si ṣe, nigbati diẹ ninu wọn ba kọ ṣubu, ẹnikẹni ti o ba gbọ́ yio si wipe, Iparun si mbẹ ninu awọn enia ti ntọ̀ Absalomu lẹhin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kíyèsí i, ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ nísinsin yìí ni ihò kan, tàbí ní ibòmíràn: yóò sì ṣe, nígbà tí díẹ̀ nínú wọn bá kọ́ ṣubú, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ yóò sì wí pé, ‘Ìparun sì ń bẹ́ nínú àwọn ènìyàn tí ń tọ Ábúsálómù lẹ́yìn.’