2 Samuel 18:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Joabu dá a lóhùn pé, “Nígbà tí o rí i, kí ló dé tí o kò pa á níbẹ̀ lẹsẹkẹsẹ? Inú mi ìbá dùn láti fún ọ ní owó fadaka mẹ́wàá ati ìgbànú akikanju ninu ogun jíjà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joabu si wi fun ọkunrin na ti o sọ fun u pe, Sa wõ, iwọ ri i, eha ti ṣe ti iwọ kò fi lù u bolẹ nibẹ? emi iba si fun ọ ni ṣekeli fadaka mẹwa, ati amure kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jóábù sì wí fún ọkùnrin náà tí ó sọ fún un pé, “Sá wò ó, ìwọ rí i, èéha ti ṣe tí ìwọ kò fi lù ú bolẹ̀ níbẹ̀? Èmi ìbá sì fún ọ ní ṣékélì fàdákà mẹ́wàá, àti àmùrè kan.”