2 Samuel 18:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ọmọ ogun náà dáhùn pé, “Ò báà tilẹ̀ fún mi ní ẹgbẹrun (1,000) owó fadaka, n kò ní ṣíwọ́ sókè pa ọmọ ọba. Gbogbo wa ni a gbọ́, nígbà tí ọba pàṣẹ fún ìwọ ati Abiṣai ati Itai pé, nítorí ti òun ọba, kí ẹ má pa Absalomu lára.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin na si wi fun Joabu pe, Biotilẹṣepe emi o gba ẹgbẹrun ṣekeli fadaka si ọwọ́ mi, emi kì yio fi ọwọ́ mi kan ọmọ ọba: nitoripe awa gbọ́ nigbati ọba kilọ fun iwọ ati Abiṣai, ati Ittai, pe, Ẹ kiye si i, ki ẹnikẹni ki o má fi ọwọ́ kan ọdọmọkunrin na Absalomu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin náà sì wí fún Jóábù pé, “Bí èmi tilẹ̀ gba ẹgbẹ̀rún ṣékélì fàdákà sí ọwọ́ mí, èmi kì yóò fi ọwọ́ mi kan ọmọ ọba: nítorí pé àwa gbọ́ nígbà tí ọba kìlọ̀ fún ìwọ àti Ábíṣáì, àti Ítaì, pé, ‘Ẹ kíyèsí i, kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi ọwọ́ kan ọ̀dọ́mọkùnrin náà Ábúsálómù.’