2 Samuel 18:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Joabu dáhùn pé, “N kò ní máa fi àkókò mi ṣòfò, kí n sọ pé mò ń bá ọ sọ̀rọ̀.” Joabu bá mú ọ̀kọ̀ mẹta, ó sọ wọ́n lu Absalomu ní igbá àyà lórí igi oaku tí ó há sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joabu si wipe, emi kì yio duro bẹ̃ niwaju rẹ. O si mu ọ̀kọ mẹta lọwọ rẹ̀, o si fi wọn gun Absalomu li ọkàn, nigbati o si wà lãye li agbedemeji igi pọ́nhan na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jóábù sì wí pé, “Èmi kì yóò dúró bẹ́ẹ̀ níwájú rẹ.” Ó sì mú ọ̀kọ̀ mẹ́ta lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ́n gún Ábúsálómù ní ọkàn, nígbà tí ó sì wà láàyè ní agbede-méjì igi óákù náà.