2 Samuel 18:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, Joabu fọn fèrè ogun, kí wọ́n dáwọ́ ogun jíjà dúró. Àwọn ọmọ ogun Dafidi bá pada lẹ́yìn àwọn ọmọ ogun Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joabu si fún ipè, awọn enia na si yipada ati mã lepa Israeli: nitori Joabu ti pe awọn enia na pada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jóábù sì fun ìpè, àwọn ènìyàn náà sì yípadà láti máa lépa Ísírẹ́lì: nítorí Jóábù ti pe àwọn ènìyàn náà padà.