2 Samuel 18:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n gbé òkú Absalomu jù sinu ihò jíjìn kan ninu igbó, wọ́n sì kó ọpọlọpọ òkúta jọ sórí òkú rẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá sá, olukuluku gba ilé rẹ̀ lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si gbe Absalomu, nwọn si sọ ọ sinu iho nla kan ni igbogàn na, nwọn si papó okuta pupọ jọ si i lori, gbogbo Israeli si sa, olukuluku si inu agọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì gbé Ábúsálómù, wọ́n sì sọ ọ́ sínú ihò ńlá kan ní igbó náà, wọ́n sì kó òkúta púpọ̀ jọ sí i lórí, gbogbo Ísírẹ́lì sì sá, olúkúlùkù sí inú àgọ́ rẹ̀.