2 Samuel 18:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, ó rán wọn jáde ní ìpín mẹta, ó fi Joabu, ati Abiṣai, ọmọ Seruaya, àbúrò Joabu, ati Itai, ará Gati, ṣe ọ̀gágun àgbà ìpín kọ̀ọ̀kan. Ó ní òun pàápàá yóo bá wọn lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si fi idamẹta awọn enia na le Joabu lọwọ, o si ran wọn lọ, ati idamẹta le Abiṣai ọmọ Seruia aburo Joabu lọwọ, ati idamẹta le Ittai ara Giti lọwọ. Ọba si wi fun awọn enia na pe, nitotọ emi tikara mi o si ba nyin lọ pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì fi ìdámẹ́ta àwọn ènìyàn náà lé Jóábù lọ́wọ́, ó sì rán wọn lọ, àti ìdámẹ́ta lé Ábíṣáì ọmọ Serúíà àbúrò Jóábù lọ́wọ́ àti ìdàmẹ́ta lè Ítaì ará Gítì lọ́wọ́, Ọba sì wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Nítòótọ́ èmi tìkárami yóò sì bá yín lọ pẹ̀lú.”