2 Samuel 18:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Joabu dá a lóhùn pé, “Rárá o, kì í ṣe ìwọ ni o óo mú ìròyìn náà lọ lónìí, bí ó bá di ọjọ́ mìíràn, o lè mú ìròyìn ayọ̀ lọ. Kì í ṣe òní, nítorí pé ọmọ ọba ni ó kú.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joabu si wi fun u pe, Iwọ ki yio mu ìhin lọ loni, ṣugbọn iwọ o mu ìhin lọ ni ijọ miran: ṣugbọn loni yi iwọ kì yio mu ìhin kan lọ, nitoriti ọmọ ọba ṣe alaisi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jóábù sì wí fún un pé, “Ìwọ kì yóò mù ìhìn lọ lónìí, ṣùgbọ́n ìwọ ó mú lọ ní ijọ́ mìíràn: ṣùgbọ́n lónìí yìí ìwọ kì yóò mú ìhìn kan lọ, nítorí tí ọmọ Ọba ṣe aláìsí.”