2 Samuel 18:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀ṣọ́ náà tún rí ẹyọ ẹnìkan, tí òun náà ń sáré bọ̀. Ó tún ké sí ẹ̀ṣọ́ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà, ó ní, “Wò ó, ẹnìkan ni ó tún ń sáré bọ̀ yìí.” Ọba dáhùn pé, “Ìròyìn ayọ̀ ni òun náà ń mú bọ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Alore na si ri ọkunrin miran ti nsare: alore si kọ si ẹniti nṣọ bode, o si wi pe, Wõ, ọkunrin kan nsare on nikan, ọba si wipe, Eyi na pẹlu nmu ihìn rere wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Álóre náà sì rí ọkùnrin mìíràn tí ń sáré: Alóre sì kọ sí ẹni tí ń ṣọ́ bodè, ó sì wí pe, “Wò ó, ọkùnrin kan ń sáré òun nìkan.” Ọba sì wí pé, “Èyí náà pẹ̀lú ń mú ìhìn rere wá.”