2 Samuel 18:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀ṣọ́ tún ní, “Ẹni tí ó ṣáájú tí mo rí yìí jọ Ahimaasi.” Ọba dáhùn pé, “Eniyan dáradára ni, ìròyìn ayọ̀ ni ó sì ń mú bọ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Alore na si wipe, Emi wo isare ẹniti o wà niwaju o dabi isare Ahimaasi ọmọ Sadoku. Ọba si wi pe, Enia rere ni, o si nmu ihìn rere wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Álóre náà sì wí pé, “Èmi wo ìsáre ẹni tí ó wà níwájú ó dàbí ìsáré Áhímásì ọmọ Sádókù.” Ọba sì wí pé, “Ènìyàn re ni, ó sì ń mú ìhìn rere wá!”