2 Samuel 18:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé nǹkankan kò ṣe Absalomu ọmọ mi?” Ahimaasi dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, nígbà tí Joabu fi ń rán mi bọ̀, gbogbo nǹkan dàrú, ó sì rí rúdurùdu, nítorí náà n kò lè sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gan-an.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si bere pe, Alafia fun Absalomu ọmọdekunrin nì bi? Ahimaasi si dahun pe, Nigbati Joabu rán iranṣẹ ọba, ati emi iranṣẹ rẹ, mo ri ọ̀pọ enia, ṣugbọn emi kò mọ̀ idi rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì béèrè pé, “Àlàáfíà ha wà fún Ábúsálómù, ọmọdékùnrin náà bí?” Áhímásì sì dáhùn pé, “Nígbà tí Jóábù rán ìránṣẹ́ ọba, àti èmi ìránṣẹ́ rẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n èmi kò mọ ìdí rẹ̀.”