2 Samuel 18:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn wọ́n dá a lóhùn pé, “O kò ní bá wa lọ, nítorí pé bí a bá sá lójú ogun ní tiwa, tabi tí ìdajì ninu wa bá kú, kò jẹ́ ohunkohun fún àwọn ọ̀tá wa. Ṣugbọn ìwọ nìkan ju ẹgbaarun (10,000) wa lọ. Ohun tí ó dára ni pé kí o dúró ní ìlú, kí o sì máa fi nǹkan ranṣẹ sí wa láti fi ràn wá lọ́wọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn enia na si wipe, Iwọ ki yio ba wa lọ: nitoripe bi awa ba sa, nwọn kì yio nani wa, tabi bi o tilẹ ṣepe idajì wa kú, nwọn ki yio nani wa, nitoripe iwọ nikan to ẹgbãrun wa: nitorina, o si dara ki iwọ ki o ma ràn wa lọwọ lati ilu wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn náà sì wí pé, “Ìwọ kì yóò bá wa lọ: nítorí pé bí àwa bá sá, wọn kì yóò náání wa, tàbí bí ó tílẹ̀ ṣe pé ìdajì wa kú, wọn kì yóò násní wa, nítorí pé ìwọ nìkan tó ẹgbàarún wa: nítorí náà, ó sì dára kí ìwọ máa ràn wá lọ́wọ́ láti ìlú wá.”