2 Samuel 18:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba dáhùn pé, “Ohunkohun tí ẹ bá ní kí n ṣe náà ni n óo ṣe.” Ọba bá dúró ní ẹnu ibodè, bí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí ń tò kọjá lọ ní ọgọọgọrun-un (100) ati ẹgbẹẹgbẹrun (1,000).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si wi fun wọn pe, Eyi ti o ba tọ́ loju nyin li emi o ṣe. Ọba si duro li apakan ẹnu odi, gbogbo awọn enia na si jade ni ọ̀rọrún ati ni ẹgbẹgbẹrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì wí fún wọn pé, “Èyí tí ó bá tọ́ lójú yin ni èmi ó ṣe.” Ọba sì dúró ní apákan ẹnu odi, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì jáde ní ọrọrún àti ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún.