2 Samuel 18:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lójijì, Absalomu já sí ààrin àwọn ọmọ ogun Dafidi. Ìbaaka ni Absalomu gùn. Ìbaaka yìí gba abẹ́ ẹ̀ka igi Oaku ńlá kan, ẹ̀ka igi yìí sì dí tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi kọ́ Absalomu ní irun orí, Ìbaaka yọ lọ lábẹ́ rẹ̀, Absalomu sì ń rọ̀ dirodiro nítorí pé ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tólẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Absalomu si pade awọn iranṣẹ Dafidi. Absalomu si gun ori ibaka kan, ibaka na si gba abẹ ẹka nla igi pọ́nhan kan ti o tobi lọ, ori rẹ̀ si kọ́ igi pọ́nhan na, on si rọ̀ soke li agbedemeji ọrun on ilẹ; ibaka na ti o wà labẹ rẹ̀ si lọ kuro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábúsálómù sì pàdé àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì. Ábúsálómù sì gun orí ìbaka kan, ìbaka náà sì gba abẹ́ ẹ̀ka ńlá igi óákù kan tí ó tóbi lọ, orí rẹ̀ sì kọ́ igi óákù náà òun sì rọ̀ sókè ní agbede-méjì ọ̀run àti ilẹ̀; ìbaka náà tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sì lọ kúrò.