2 Samuel 19:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
A fi àmì òróró yan Absalomu ní ọba, ṣugbọn wọ́n ti pa á lójú ogun, nítorí náà, ó yẹ kí ẹnìkan gbìyànjú láti mú Dafidi ọba pada.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Absalomu, ti awa fi jọba lori wa si kú li ogun: njẹ ẽṣe ti ẹnyin fi dakẹ ti ẹnyin kò si sọ̀rọ kan lati mu ọba pada wá?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábúsálómù, tí àwa fi jọba lórí wa sì kú ní ogun: ǹjẹ́ èéṣe tí ẹ̀yín fi dákẹ́ tí ẹ̀yin kò sì sọ̀rọ̀ kan láti mú ọba padà wá?”