2 Samuel 19:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi ní kí wọ́n sọ fún Amasa pé, ẹbí òun ni Amasa; ati pé, láti ìgbà náà lọ, Amasa ni òun yóo fi ṣe balogun òun, dípò Joabu. Ó búra pé kí Ọlọrun pa òun bí òun kò bá ṣe bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹnyin ki o si wi fun Amasa pe, Egungun ati ẹran ara mi ki iwọ iṣe bi? ki Ọlọrun ki o ṣe bẹ̃ si mi ati ju bẹ̃ lọ pẹlu, bi iwọ kò ba ṣe olori ogun niwaju mi titi, ni ipò Joabu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ẹ̀yin sì wí fún Ámásà pé, ‘Egungun àti ẹran ara mi kọ́ ni ìwọ jẹ́ bí? Kí Ọlọ́run ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ kò ba ṣe olórí ogun níwájú mi títí, ní ipò Jóábù.’ ”