2 Samuel 19:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹgbẹrun (1,000) eniyan, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ni ó kó lọ́wọ́. Siba, iranṣẹ ìdílé Saulu, náà wá pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀ mẹẹdogun, ati ogún iranṣẹ. Wọ́n dé sí etí odò kí ọba tó dé ibẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹgbẹrun ọmọkunrin si wà lọdọ rẹ̀ ninu awọn ọmọkunrin Benjamini, Siba iranṣẹ ile Saulu, ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ mẹ̃dogun ati ogún iranṣẹ si pẹlu rẹ̀; nwọn si goke odo Jordani ṣaju ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹgbẹ̀rún ọmọkùnrin sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú àwọn ọmọkùnrin Bẹ́ńjámínì, Ṣíbà ìránṣẹ́ ilé Ṣọ́ọ̀lù, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ẹ̀dógún àti ogún ìránṣẹ́ sì pẹ̀lú rẹ̀; wọ́n sì gòkè odò Jódánì ṣáájú ọba.