2 Samuel 19:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo mọ̀ pé mo ti ṣẹ̀; Ìdí nìyí, tí ó fi jẹ́ pé èmi ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́ wá pàdé rẹ lónìí, ninu gbogbo ìdílé Josẹfu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe iranṣẹ rẹ mọ̀ pe on ti ṣẹ̀; si wõ, ni gbogbo idile Josefu emi li o kọ́ wá loni lati sọkalẹ wá pade oluwa mi ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé èmi ti ṣẹ̀; sì wòó, mo wá lónìí yìí, ẹni àkọ́kọ́ ní gbogbo ìdílé Jósẹ́fù tí yóò sọ̀kalẹ̀ wá pàdé OLÚWA mi ọba.”