2 Samuel 19:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Abiṣai ọmọ Seruaya dáhùn pé, “Pípa ni ó yẹ kí á pa Ṣimei nítorí pé ó ṣépè lé ẹni tí OLUWA fi òróró yàn ní ọba.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Abiṣai ọmọ Seruia dahùn o si wipe, Kò ha tọ́ ki a pa Ṣimei nitori eyi? nitoripe on ti bú ẹni-àmi-ororo Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Ábíṣáì ọmọ Serúíà dáhùn ó sì wí pé, “Kò há tọ́ kí a pa Síméì nítorí èyí? Nítorí pé òun ti bú ẹni àmì òróró OLÚWA.”