2 Samuel 19:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mẹfiboṣẹti dáhùn pé, “Kabiyesi, gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà ti mọ̀, arọ ni mí. Mo sọ fún iranṣẹ mi pé kí ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mi ní gàárì, kí n lè gùn ún tẹ̀lé ọ, ṣugbọn ó hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si dahùn wipe, Oluwa mi, ọba, iranṣẹ mi li o tàn mi jẹ; nitoriti iranṣẹ rẹ ti wipe, Emi o di kẹtẹkẹtẹ ni gãri, emi o gùn u, emi o si tọ̀ ọba lọ, nitoriti iranṣẹ rẹ yarọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun sì dáhùn wí pé, “OLÚWA mi, Ọba, ìránṣẹ́ mi ni ó tàn mí, nítorí ìránṣẹ́ rẹ wí fún un pé, ‘Di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi èmi ó gùn ún, èmi ó sì tọ ọba lọ.’ Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ yarọ.