2 Samuel 19:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo ìdílé baba mi pátá ni ó yẹ kí o pa, ṣugbọn o gbà mí láàyè; o sì fún mi ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹun níbi tabili rẹ. Kò yẹ mí rárá, láti tún bèèrè nǹkankan mọ́ lọ́wọ́ kabiyesi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe gbogbo ile baba mi bi okú enia ni nwọn sa ri niwaju oluwa mi ọba: iwọ si fi ipò fun iranṣẹ rẹ larin awọn ti o njẹun ni ibi onjẹ rẹ. Nitorina are kili emi ni ti emi o fi ma ke pe ọba sibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé gbogbo ilé baba mi bí òkú ènìyàn ni wọ́n sáà rí níwájú OLÚWA mi ọba: ìwọ sì fi ipò fún ìránṣẹ́ rẹ láàrin àwọn tí ó ń jẹ́un ní ibi oúnjẹ́. Nítorí náà àre kín ni èmi ní tí èmi yóò fi máa ké pe ọba síbẹ̀.”