2 Samuel 19:35 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo ti di ẹni ọgọrin ọdún, kò sì sí ohunkohun tí ó tún wù mí mọ́. Oúnjẹ ati ohun mímu kò dùn lẹ́nu mi mọ́. Bí àwọn akọrin ń kọrin, n kò lè gbọ́ orin wọn mọ́. Wahala lásán ni n óo lọ kó bá oluwa mi, ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹni ogbó ọgọrin ọdun sa li emi loni: emi le mọ̀ iyatọ ninu rere ati buburu? iranṣẹ rẹ le mọ̀ adùn ohun ti emi njẹ tabi ohun ti emi nmu bi? emi tun le mọ̀ adùn ohùn awọn ọkunrin ti nkọrin, ati awọn obinrin ti nkọrin bi? njẹ nitori kili iranṣẹ rẹ yio ṣe jẹ́ iyọnu sibẹ fun oluwa mi ọba?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni ogbó ọgọ́rin ọdún sáà ni èmi lónìí: ǹjẹ́ èmi mọ ìyàtọ̀ nínú rere àti búburú? Ǹjẹ́ ìránṣẹ́ rẹ ló mọ adùn ohun tí òun ń jẹ tàbí ohun ti òun ń mu bí? Èmi tún lè mọ adùn ohùn àwọn ọkùnrin tí ń kọrin àti àwọn obìnrin tí ń kọ́rin bí, ǹjẹ́ nítorí kínni ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe jẹ́ ìyọnu síbẹ̀ fún OLÚWA mi ọba.