2 Samuel 19:37 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n pada lọ sí ilé mi, kí n lè kú sí ìlú mi, nítòsí ibojì àwọn òbí mi. Kimhamu ọmọ mi nìyí, jẹ́ kí ó máa bá ọ lọ, kí o sì ṣe ohun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ fún un.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹ rẹ pada, emi o si kú ni ilu mi, a o si sin mi ni iboji baba ati iya mi. Si wo Kimhamu iranṣẹ rẹ, yio ba oluwa mi ọba goke; iwọ o si ṣe ohun ti o ba tọ li oju rẹ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ padà, èmi ó sì kú ní ìlú mi, a ó sì sin mí ní ibojì baba àti ìyá mi. Sì wo Kimhámù ìránṣẹ́ rẹ, yóò bá OLÚWA mi ọba gòkè; ìwọ ó sì ṣe ohun tí ó bá tọ́ lójú rẹ fún un.”