2 Samuel 19:39 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà ni Dafidi ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ gòkè odò Jọdani. Ó kí Basilai, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì súre fún un; Basilai bá pada sí ilé rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn enia si goke odo Jordani. Ọba si goke; ọba si fi ẹnu kò Barsillai li ẹnu, o si sure fun u; on si pada si ile rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ènìyàn sì gòkè odò Jódánì ọba sì gòkè; ọba sì fi ẹnu ko Básíláì lẹ́nu, ó sì súre fún un; òun sì padà sí ilé rẹ̀.