2 Samuel 19:41 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì bi í pé, “Kabiyesi, kí ló dé tí àwọn eniyan Juda, àwọn arakunrin wa, fi lérò pé àwọn ní ẹ̀tọ́ láti mú ọ lọ, ati láti sin ìwọ ati ìdílé rẹ, ati àwọn eniyan rẹ kọjá odò Jọdani?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wõ, gbogbo awọn ọkunrin Israeli si tọ ọba wá, nwọn si wi fun ọba pe, Ẽṣe ti awọn arakunrin wa awọn ọkunrin Juda fi ji ọ kuro, ti nwọn si fi mu ọba ati awọn ara ile rẹ̀ goke odo Jordani, ati gbogbo awọn enia Dafidi pẹlu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sì wò ó, gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì tọ ọba wá, wọ́n sì wí fún ọba pé, “Èéṣe tí àwọn arákùnrin wa àwọn ọkùnrin Júdà fi jí ọ kúrò, tí wọ́n sì fi mú ọba àti àwọn ará ilé rẹ̀ gòkè odò Jódánì, àti gbogbo àwọn ènìyàn Dáfídì pẹ̀lú rẹ?”