2 Samuel 19:42 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn eniyan Juda bá dáhùn pé, “Ìdí tí a fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, ọ̀kan náà ni àwa ati ọba. Kí ló dé tí èyí fi níláti bà yín ninu jẹ́? Kì í ṣá ṣe pé òun ni ó ń bọ́ wa, a kò sì gba nǹkankan lọ́wọ́ rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ọkunrin Juda si da awọn ọkunrin Israeli li ohùn pe, Nitoripe ọba bá wa tan ni; ẽṣe ti ẹnyin fi binu nitori ọran yi? awa jẹ ninu onjẹ ọba rara bi? tabi o fi ẹ̀bun kan fun wa bi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ọkùnrin Júdà sì dá àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì lóhùn pé, “Nítorí pé ọba bá wa tan ni; èéṣe tí ẹ̀yin fi bínú nítorí ọ̀ràn yìí? Àwa jẹ nínú òúnjẹ ọba rárá bí? Tàbí ó fi ẹ̀bùn kan fún wa bí?”