2 Samuel 19:43 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli dáhùn pé, “Ìlọ́po mẹ́wàá ẹ̀tọ́ tí ẹ ní sí ọba ni àwa ní, kì báà tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kan náà ni yín. Kí ló dé tí ẹ fi fi ojú tẹmbẹlu wa? Ẹ má gbàgbé pé àwa ni a dábàá ati mú ọba pada sílé.” Ṣugbọn ọ̀rọ̀ àwọn ará ilẹ̀ Juda le ju ti àwọn ará ilẹ̀ Israẹli lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọkunrin Israeli si da awọn ọkunrin Juda li ohùn pe, Awa ni ipa mẹwa ninu ọba, awa si ni ninu Dafidi jù nyin lọ, ẽṣe ti ẹnyin kò fi kà wa si, ti ìmọ wa kò fi ṣaju lati mu ọba wa pada? ọ̀rọ awọn ọkunrin Juda si le jù ọ̀rọ awọn ọkunrin Israeli lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì náà sì dá àwọn ọkùnrin Júdà lóhùn pé, “Àwa ní ipá mẹ́wàá nínú ọba, àwa sì ní nínú Dáfídì jù yín lọ, èésì ṣe tí ẹ̀yin kò fi kà wá sí, tí ìmọ̀ wa kò fi ṣáájú láti mú ọba wa padà?” Ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Júdà sì le ju ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì.