2 Samuel 19:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
nítorí pé o fẹ́ràn àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ, o sì kórìíra àwọn tí wọ́n fẹ́ràn rẹ. O ti fihàn gbangba pé, àwọn ọ̀gágun ati ọmọ ogun rẹ kò jẹ́ nǹkankan lójú rẹ. Mo ti rí i gbangba lónìí pé, ìbá dùn mọ́ ọ ninu, bí gbogbo wa tilẹ̀ kú, tí Absalomu sì wà láàyè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe iwọ fẹ awọn ọta rẹ, iwọ si korira awọn ọrẹ rẹ. Nitoriti iwọ wi loni pe, Iwọ kò nani awọn ọmọ ọba, tabi awọn iranṣẹ: emi si ri loni pe, ibaṣepe Absalomu wà lãye, ki gbogbo wa si kú loni, njẹ iba dùnmọ ọ gidigidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé ìwọ fẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ, ìwọ sì kóríra àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Nítorí tí ìwọ wí lónìí pé, Ìwọ kò náání àwọn ọmọ ọba tàbí àwọn ìránṣẹ́; èmi sì rí lónìí pé, ìbáṣe pé Ábúsálómù wà láàyè, kí gbogbo wa sì kú lónìí, ǹjẹ́ ìbá dùn mọ́ ọ gidigidi.