2 Samuel 19:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọba bá dìde, ó lọ jókòó lẹ́bàá ẹnu ọ̀nà ibodè. Àwọn eniyan rẹ̀ gbọ́ pé ó wà níbẹ̀, gbogbo wọn bá wá rọ̀gbà yí i ká. Ní àkókò yìí, gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli ti sá, olukuluku ti pada sí ilé rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si dide, o si joko li ẹnu ọ̀na. Nwọn si wi fun gbogbo awọn enia na pe, Wõ, ọba joko li ẹnu ọ̀na. Gbogbo enia si wá si iwaju ọba: nitoripe, Israeli ti sa, olukuluku si àgọ́ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì dìde, ó sì jókòó ní ẹnu ọ̀nà, Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, “Wò ó, ọba jókòó lẹ́nu ọ̀nà.” Gbogbo ènìyàn sì wá sí iwájú Ọba: nítorí pé, Ísírẹ́lì ti sá, olúkúlukú sí àgọ́ rẹ̀.