2 Samuel 19:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli káàkiri. Wọ́n ń wí láàrin ara wọn pé, “Ọba Dafidi ni ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, òun ni ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Filistia, ṣugbọn nisinsinyii, ó ti sá kúrò nílùú fún Absalomu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn enia na si mba ara wọn jà ninu gbogbo ẹya Israeli, pe, Ọba ti gbà wa là lọwọ awọn ọta wa, o si ti gbà wa kuro lọwọ awọn Filistini; on si wa sa kuro ni ilu nitori Absalomu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì ń bà ara wọn jà nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, pé, “Ọba ti gbà wá là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, ó sì ti gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Fílístínì; òun sì wá sá kúrò ní ìlú nítorí Ábúsálómù.